Rom 3:20-25
Rom 3:20-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin, a kì yóò dá ẹnikẹ́ni láre níwájú rẹ̀: nítorí nípa òfin ni ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ti wá. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, a ti fi òdodo Ọlọ́run hàn láìsí òfin, tí a ti ń jẹ́rìí sí nípa òfin àti nípa àwọn wòlíì; Àní òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, sí gbogbo ènìyàn àti gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́: nítorí tí kò sí ìyàtọ̀ láàrín Júù àti Helleni. Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run: Àwọn ẹni tí a ń dá láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, nípa ìdáǹdè tí ó wà nínú Kristi Jesu: Ẹni tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ láti jẹ́ ètùtù nípa ìgbàgbọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, láti fi òdodo rẹ̀ hàn nítorí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá, nínú ìpamọ́ra Ọlọ́run
Rom 3:20-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá. Ṣugbọn nisisiyi a ti fi ododo Ọlọrun hàn laisi ofin, ti a njẹri si nipa ofin ati nipa awọn woli; Ani ododo Ọlọrun nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, si gbogbo enia, ati lara gbogbo awọn ti o gbagbọ́: nitoriti kò si ìyatọ: Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun; Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu: Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun
Rom 3:20-26 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀, bí a bá mú Òfin tí a fi díwọ̀n iṣẹ́ ọmọ eniyan, kò sí ẹ̀dá kan tí a óo dá láre níwájú Ọlọrun. Nítorí òfin níí mú kí eniyan mọ ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre ti hàn láìsí Òfin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ti Òfin ati ti àwọn wolii Ọlọrun jẹ́rìí sí i. Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan. Nítorí gbogbo eniyan ló ti dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun. Gbogbo wọn ni Ọlọrun ti ṣe lóore: ó dá wọn láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìràpadà tí Kristi Jesu ṣe. Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre.