ÌFIHÀN 8:1-5

ÌFIHÀN 8:1-5 YCE

Nígbà tí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tú èdìdì keje, gbogbo ohun tí ó wà ní ọ̀run parọ́rọ́ fún bí ìdajì wakati kan. Mo bá rí àwọn angẹli meje tí wọn máa ń dúró níwájú Ọlọrun, a fún wọn ní kàkàkí meje. Angẹli mìíràn tún dé, ó dúró lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ. Ó mú àwo turari tí wọ́n fi wúrà ṣe lọ́wọ́. A fún un ní turari pupọ kí ó fi rúbọ pẹlu adura gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun lórí pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú ìtẹ́ náà. Èéfín turari ati adura àwọn eniyan Ọlọrun gòkè lọ siwaju Ọlọrun láti ọwọ́ angẹli náà. Angẹli náà bá mú àwo turari yìí, ó bu iná láti orí pẹpẹ ìrúbọ kún inú rẹ̀, ó bá jù ú sí orí ilẹ̀ ayé. Ààrá bá bẹ̀rẹ̀ sí sán, mànàmáná ń kọ, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì.