Ifi 8:1-5
Ifi 8:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì keje, ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ̀n ààbọ̀ wákàtí kan. Mo sì rí àwọn angẹli méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn. Angẹli mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fi kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́. Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́ sì gòkè lọ síwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ angẹli náà wá. Angẹli náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé: A sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì.
Ifi 8:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI o si ṣí èdidi keje, kẹ́kẹ́ pa li ọrun niwọn àbọ wakati kan. Mo si ri awọn angẹli meje ti nwọn duro niwaju Ọlọrun; a si fi ipè meje fun wọn. Angẹli miran si wá, o si duro tì pẹpẹ, o ni awo turari wura kan; a si fi turari pupọ̀ fun u, ki o le fi i kún adura gbogbo awọn enia mimọ́ lori pẹpẹ wura ti mbẹ niwaju itẹ́. Ati ẹ̃fin turari na pẹlu adura awọn enia mimọ́ si gòke lọ siwaju Ọlọrun lati ọwọ́ angẹli na wá. Angeli na si mu awo turari na, o si fọ̀n iná ori pẹpẹ kun u, o si dà a sori ilẹ aiye: a si gbọ ohùn, ãra si san, mànamána si kọ, ìṣẹlẹ si ṣẹ̀.
Ifi 8:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí Ọ̀dọ́ Aguntan náà tú èdìdì keje, gbogbo ohun tí ó wà ní ọ̀run parọ́rọ́ fún bí ìdajì wakati kan. Mo bá rí àwọn angẹli meje tí wọn máa ń dúró níwájú Ọlọrun, a fún wọn ní kàkàkí meje. Angẹli mìíràn tún dé, ó dúró lẹ́bàá pẹpẹ ìrúbọ. Ó mú àwo turari tí wọ́n fi wúrà ṣe lọ́wọ́. A fún un ní turari pupọ kí ó fi rúbọ pẹlu adura gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun lórí pẹpẹ ìrúbọ wúrà tí ó wà níwájú ìtẹ́ náà. Èéfín turari ati adura àwọn eniyan Ọlọrun gòkè lọ siwaju Ọlọrun láti ọwọ́ angẹli náà. Angẹli náà bá mú àwo turari yìí, ó bu iná láti orí pẹpẹ ìrúbọ kún inú rẹ̀, ó bá jù ú sí orí ilẹ̀ ayé. Ààrá bá bẹ̀rẹ̀ sí sán, mànàmáná ń kọ, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì.