Ẹ kọ orin titun sí OLUWA, nítorí tí ó ti ṣe ohun ìyanu; agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ati apá mímọ́ rẹ̀ ni ó fi ṣẹgun. OLUWA ti sọ ìṣẹ́gun rẹ̀ di mímọ̀, ó ti fi ìdáláre rẹ̀ hàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè. Ó ranti ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli; gbogbo ayé ti rí ìṣẹ́gun Ọlọrun wa. Gbogbo ayé, ẹ hó ìhó ayọ̀ sí OLUWA; ẹ bú sí orin ayọ̀, kí ẹ sì kọ orin ìyìn. Ẹ fi hapu kọ orin ìyìn sí OLUWA, àní, hapu ati ohùn orin dídùn. Ẹ fun fèrè ati ìwo kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀ níwájú OLUWA Ọba. Kí òkun ó hó, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, kí ayé hó, ati àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Kà ORIN DAFIDI 98
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 98:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò