ORIN DAFIDI 92

92
Orin Ìyìn
1Ó dára kí eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, OLUWA;
kí ó sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá Ògo;
2ó dára kí eniyan máa kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ní òwúrọ̀,
kí ó máa kéde òtítọ́ rẹ ní alẹ́,
3pẹlu orin, lórí ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá,
ati hapu.
4Nítorí ìwọ, OLUWA, ti mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ;
OLUWA, mò ń fi ayọ̀ kọrin nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
5Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA!
Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ!
6Òpè eniyan kò lè mọ̀,
kò sì le yé òmùgọ̀:#Ọgb 13:1
7pé bí eniyan burúkú bá tilẹ̀ rú bíi koríko,
tí gbogbo àwọn aṣebi sì ń gbilẹ̀,
ó dájú pé ìparun ayérayé ni òpin wọn.
8Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA.
9Wò ó, OLUWA, àwọn ọ̀tá rẹ yóo parun;
gbogbo àwọn aṣebi yóo sì fọ́n ká.
10Ṣugbọn o ti gbé mi ga, o ti fún mi lágbára bíi ti ẹfọ̀n;
o ti da òróró dáradára sí mi lórí.
11Mo ti fi ojú mi rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi,
mo sì ti fi etí mi gbọ́ ìparun àwọn ẹni ibi tí ó gbé ìjà kò mí.
12Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ,
wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni.
13Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA,
tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa.
14Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn,
wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo;
15láti fihàn pé olóòótọ́ ni OLUWA;
òun ni àpáta mi, kò sì sí aiṣododo lọ́wọ́ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 92: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀