ORIN DAFIDI 91:14-16

ORIN DAFIDI 91:14-16 YCE

OLUWA ní, “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí mi, n óo gbà á là; n óo dáàbò bò ó, nítorí pé ó mọ orúkọ mi. Yóo pè mí, n óo sì dá a lóhùn; n óo wà pẹlu rẹ̀ ninu ìṣòro, n óo yọ ọ́ ninu rẹ̀, n óo dá a lọ́lá. N óo fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn, n óo sì gbà á là.”