O. Daf 91:14-16
O. Daf 91:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ti o fẹ ifẹ rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ṣe gbà a: emi o gbé e leke, nitori ti o mọ̀ orukọ mi. On o pè orukọ mi, emi o si da a lohùn: emi o pẹlu rẹ̀ ninu ipọnju, emi o gbà a, emi o si bu ọlá fun u. Ẹmi gigun li emi o fi tẹ́ ẹ lọrun, emi o si fi igbala mi hàn a.
O. Daf 91:14-16 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí mi, n óo gbà á là; n óo dáàbò bò ó, nítorí pé ó mọ orúkọ mi. Yóo pè mí, n óo sì dá a lóhùn; n óo wà pẹlu rẹ̀ ninu ìṣòro, n óo yọ ọ́ ninu rẹ̀, n óo dá a lọ́lá. N óo fi ẹ̀mí gígùn tẹ́ ẹ lọ́rùn, n óo sì gbà á là.”
O. Daf 91:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́; èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi. Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn; èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú, èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”