ORIN DAFIDI 9:1-12

ORIN DAFIDI 9:1-12 YCE

OLUWA, tọkàntọkàn ni n óo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ; n óo ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ. N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ; n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ. Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà, wọ́n ṣubú, wọ́n sì parun níwájú rẹ. Nítorí ìwọ ni o fi ìdí ẹ̀tọ́ mi múlẹ̀, tí o sì dá mi láre; ìwọ ni o jókòó lórí ìtẹ́, o sì ṣe ìdájọ́ òdodo. O bá àwọn orílẹ̀-èdè wí, o pa àwọn eniyan burúkú run, o sì pa orúkọ wọn rẹ́ títí lae. O pa àwọn ọ̀tá run patapata, o sọ ìlú wọn di ahoro, o sì sọ wọ́n di ẹni ìgbàgbé. Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae, ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé, yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú. Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ; nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀. Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni! Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè! Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti, kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.