O. Daf 9:1-12
O. Daf 9:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o fi gbogbo aiya mi yìn Oluwa: emi o fi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ hàn. Emi o yọ̀, emi o si ṣe inu-didùn ninu rẹ, emi o si kọrin iyìn si orukọ rẹ, iwọ Ọga-ogo julọ. Nigbati awọn ọta mi ba pẹhinda, nwọn o ṣubu, nwọn o si ṣegbe ni iwaju rẹ. Nitori iwọ li o ti mu idajọ mi ati idi ọ̀ran mi duro; iwọ li o joko lori itẹ́, ti o nṣe idajọ ododo. Iwọ ba awọn orilẹ-ède wi, iwọ pa awọn enia buburu run, iwọ pa orukọ wọn rẹ́ lai ati lailai. Niti ọta, iparun wọn pari tan lailai: iwọ li o si ti run ilu wọnni; iranti wọn si ti ṣegbe pẹlu wọn. Ṣugbọn Oluwa yio wà titi lailai: o ti tẹ́ itẹ́ rẹ̀ silẹ fun idajọ. On o si ṣe idajọ aiye li ododo, yio ṣe idajọ fun awọn enia li otitọ ìwa. Oluwa ni yio ṣe àbo awọn ẹni-inilara, àbo ni igba ipọnju. Awọn ti o si mọ̀ orukọ rẹ o gbẹkẹ le ọ: nitori iwọ, Oluwa, kò ti ikọ̀ awọn ti nṣe afẹri rẹ silẹ. Ẹ kọrin iyìn si Oluwa, ti o joko ni Sioni: ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia. Nigbati o wadi ẹjọ-ẹ̀jẹ, o ranti wọn: on kò si gbagbe ẹkún awọn olupọnju.
O. Daf 9:1-12 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, tọkàntọkàn ni n óo fi dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ; n óo ròyìn gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ. N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ; n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ. Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà, wọ́n ṣubú, wọ́n sì parun níwájú rẹ. Nítorí ìwọ ni o fi ìdí ẹ̀tọ́ mi múlẹ̀, tí o sì dá mi láre; ìwọ ni o jókòó lórí ìtẹ́, o sì ṣe ìdájọ́ òdodo. O bá àwọn orílẹ̀-èdè wí, o pa àwọn eniyan burúkú run, o sì pa orúkọ wọn rẹ́ títí lae. O pa àwọn ọ̀tá run patapata, o sọ ìlú wọn di ahoro, o sì sọ wọ́n di ẹni ìgbàgbé. Ṣugbọn OLUWA gúnwà títí lae, ó ti fi ìdí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀ múlẹ̀. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé, yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú. Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ; nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀. Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni! Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè! Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti, kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
O. Daf 9:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ó yìn ọ́, OLúWA, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi; Èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo. Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ; Èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ. Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà; Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ. Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú; ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo. Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run; Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé. Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá, Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu; àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé. OLúWA jẹ ọba títí láé; ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo; yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo. OLúWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú. Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ, nítorí, OLúWA, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀. Kọ orin ìyìn sí OLúWA, tí o ń jẹ ọba ní Sioni; kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe. Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí; òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.