ORIN DAFIDI 89:1-13

ORIN DAFIDI 89:1-13 YCE

OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae; n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran. Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae; o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run. O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹlu ẹni tí mo yàn, mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé, ‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae, n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ” Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA; kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ. Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA? Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run? Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́, o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ? OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ? OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká. Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru; nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀. Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran; o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká. Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu; ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó. Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù, òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ. Alágbára ni ọ́; agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.