O. Daf 89:1-13
O. Daf 89:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI o ma kọrin ãnu Oluwa lailai: ẹnu mi li emi o ma fi fi otitọ rẹ hàn lati irandiran. Nitori ti emi ti wipe, A o gbé ãnu ró soke lailai: otitọ rẹ ni iwọ o gbé kalẹ li ọrun. Emi ti bá ayànfẹ mi da majẹmu, emi ti bura fun Dafidi, iranṣẹ mi, Irú-ọmọ rẹ li emi o gbé kalẹ lailai, emi o si ma gbé itẹ́ rẹ ró lati irandiran, Ọrun yio si ma yìn iṣẹ-iyanu rẹ, Oluwa, otitọ rẹ pẹlu ninu ijọ enia mimọ́ rẹ. Nitori pe, tali o wà li ọrun ti a le fi wé Oluwa? tani ninu awọn ọmọ alagbara, ti a le fi wé Oluwa? Ọlọrun li o ni ìbẹru gidigidi ni ijọ enia mimọ́, o si ni ibuyìn-fun lati ọdọ gbogbo awọn ti o yi i ká. Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, tani Oluwa alagbara bi iwọ? tabi bi otitọ rẹ ti o yi ọ ká. Iwọ li o jọba ibinu okun; nigbati riru omi rẹ̀ dide, iwọ mu u pa rọrọ. Iwọ li o ti ya Rahabu pẹrẹ-pẹrẹ bi ẹniti a pa; iwọ ti fi apa ọwọ́ agbara rẹ tú awọn ọtá rẹ ká. Ọrun ni tirẹ, aiye pẹlu ni tirẹ: aiye ati ẹ̀kun rẹ̀, iwọ li o ti ṣe ipilẹ wọn. Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ. Iwọ ni apá agbara: agbara li ọwọ́ rẹ, giga li ọwọ ọtún rẹ.
O. Daf 89:1-13 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, n óo máa kọrin ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ títí lae; n óo máa fi ẹnu mi kéde òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran. Nítorí pé, a ti fi ìdí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ múlẹ̀ títí lae; o sì ti fi ìdí òtítọ́ rẹ múlẹ̀ bí ojú ọ̀run. O sọ pé, “Mo ti dá majẹmu kan pẹlu ẹni tí mo yàn, mo ti búra fún Dafidi, iranṣẹ mi, pé, ‘N óo fi ìdí àwọn ọmọ rẹ múlẹ̀ títí lae, n óo sì gbé ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ” Jẹ́ kí ojú ọ̀run máa kọrin ìyìn iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLÚWA; kí àwọn eniyan mímọ́ sì máa kọrin ìyìn òtítọ́ rẹ. Nítorí ta ni a lè fi wé ọ ní ọ̀run, OLUWA? Ta ni ó dàbí OLUWA láàrin àwọn ẹ̀dá ọ̀run? Ọlọrun, ìwọ ni a bẹ̀rù ninu ìgbìmọ̀ àwọn eniyan mímọ́, o tóbi, o sì lẹ́rù ju gbogbo àwọn tí ó yí ọ ká lọ? OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, ta ló lágbára bíi rẹ? OLUWA, òtítọ́ rẹ yí ọ ká. Ò ń jọba lórí òkun tí ń ru; nígbà tí ìgbì rẹ̀ bá ru sókè, ìwọ ni ò ń mú kí ó rọlẹ̀. Ìwọ ni o wó Rahabu mọ́lẹ̀ bí òkú ẹran; o fi ọwọ́ agbára rẹ fọ́n àwọn ọ̀tá rẹ ká. Tìrẹ ni ọ̀run, tìrẹ sì ni ayé pẹlu; ìwọ ni o tẹ ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ dó. Ìwọ ni o dá àríwá ati gúsù, òkè Tabori ati òkè Herimoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ. Alágbára ni ọ́; agbára ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; o gbé ọwọ́ agbára rẹ sókè.
O. Daf 89:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ OLúWA títí láé; pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran. Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé, pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ̀. Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi. ‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ” Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, OLúWA, òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́. Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé OLúWA? Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé OLúWA? Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi; ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká. OLúWA Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ ìwọ jẹ́ alágbára, OLúWA, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká. Ìwọ ń darí ríru omi Òkun; nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́. Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ẹni tí a pa; ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ tú àwọn ọ̀tá rẹ ká. Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ: ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀. Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn; Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ. Ìwọ ní apá agbára; agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.