ORIN DAFIDI 84:1-4

ORIN DAFIDI 84:1-4 YCE

Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí, àárò rẹ̀ ń sọ mí; tọkàn-tara ni mo fi ń kọrin ayọ̀ sí Ọlọrun alààyè. Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé, àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́ níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ọba mi, ati Ọlọrun mi. Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ, wọn óo máa kọ orin ìyìn sí ọ títí lae!