ORIN DAFIDI 81

81
Orin fún Àkókò Àsè
1Ẹ kọ orin sókè sí Ọlọrun, agbára wa;
ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọrun Jakọbu.
2Ẹ dárin, ẹ lu samba, ẹ ta hapu dídùn ati lire.
3Ẹ fọn fèrè ní ọjọ́ oṣù titun, ati ní
ọjọ́ oṣù tí a yà sọ́tọ̀, ati ní ọjọ́ àsè.#Nọm 10:10
4Nítorí pé àṣẹ ni, fún àwọn ọmọ Israẹli,
ìlànà sì ni, láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Jakọbu.
5Ó pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Josẹfu,
nígbà tí ó kọlu ilẹ̀ Ijipti.
Mo gbọ́ ohùn kan tí n kò gbọ́ rí: tí ó wí pé,
6“Mo ti sọ àjàgà náà kalẹ̀ lọ́rùn rẹ;
mo ti gba agbọ̀n ẹrù kúrò lọ́wọ́ rẹ.
7Ninu ìnira, o ké pè mí, mo sì gbà ọ́;
mo dá ọ lóhùn ninu ìjì ààrá, níbi tí mo fara pamọ́ sí;
mo sì dán ọ wò ninu omi odò Meriba.#Eks 17:7; Nọm 20:13
8Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, nígbà tí mo bá
ń kìlọ̀ fun yín,
àní kí ẹ fetí sílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
9Kò gbọdọ̀ sí ọlọrun àjèjì kan kan láàrin yín;
ẹ kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún oriṣa-koriṣa kan.#Eks 20:2-3; Diut 5:6-7
10Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín,
tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti.
Ẹ ya ẹnu yín dáradára, n óo sì bọ yín ní àbọ́yó.
11“Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò gbọ́ràn sí mi lẹ́nu,
Israẹli kò sì gba tèmi.
12Nítorí náà mo fi wọ́n sílẹ̀ sinu agídí ọkàn wọn,
kí wọn máa ṣe ohun tó wù wọ́n.
13Àwọn eniyan mi ìbá jẹ́ gbọ́ tèmi,
àní Israẹli ìbá jẹ́ máa rìn ní ọ̀nà mi!
14Kíákíá ni èmi ìbá kọjú ìjà sí àwọn ọ̀tá wọn,
tí ǹ bá sì ṣẹgun wọn.
15Àwọn tí ó kórìíra OLUWA yóo fi ìbẹ̀rùbojo tẹríba fún un,
ìyà óo sì jẹ wọ́n títí lae.
16Ṣugbọn èmi ó máa fi ọkà tí ó dára jùlọ bọ yín,
n óo sì fi oyin inú àpáta tẹ yín lọ́rùn.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 81: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀