ORIN DAFIDI 80

80
Fi Ojurere Wò Wá
1Dẹtí sílẹ̀, ìwọ olùṣọ́-aguntan Israẹli,
Ìwọ tí ò ń tọ́jú àwọn ọmọ Josẹfu bí agbo ẹran.
Ìwọ tí o gúnwà láàrin àwọn kerubu, yọ bí ọjọ́
2níwájú Efuraimu ati Bẹnjamini ati Manase.
Sọ agbára rẹ jí,
kí o sì wá gbà wá là.#Eks 25:22
3Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun;
fi ojurere wò wá,
kí á le gbà wá là.
4OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,
yóo ti pẹ́ tó, tí o óo máa bínú sí adura
àwọn eniyan rẹ?
5O ti fi omijé bọ́ wọn bí oúnjẹ,
o sì ti fún wọn ní omijé mu ní àmuyó.
6O ti mú kí àwọn aládùúgbò wa máa jìjàdù lórí wa;
àwọn ọ̀tá wa sì ń fi wá rẹ́rìn-ín láàrin ara wọn.
7Mú wa bọ̀ sípò, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun;
fi ojurere wò wá,
kí á lè là.
8O mú ìtàkùn àjàrà kan jáde láti Ijipti;
o lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, o sì gbìn ín.
9O ro ilẹ̀ fún un;
ó ta gbòǹgbò wọlẹ̀, igi rẹ̀ sì gbilẹ̀.
10Òjìji rẹ̀ bo àwọn òkè mọ́lẹ̀,
ẹ̀ka rẹ sì bo àwọn igi kedari ńláńlá;
11àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tàn kálẹ̀ títí kan òkun,
àwọn èèhù rẹ̀ sì kan odò ńlá.
12Kí ló dé tí o fi wó ògiri ọgbà rẹ̀,
tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ
sì fi ń ká èso rẹ̀?
13Àwọn ìmàdò inú ìgbẹ́ ń jẹ ẹ́ ní àjẹrun,
gbogbo àwọn nǹkan tí ń káàkiri ninu oko sì ń jẹ ẹ́.
14Jọ̀wọ́ tún yipada, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!
Bojúwolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì wò ó;
kí o sì tọ́jú ìtàkùn àjàrà yìí,
15ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn,
àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú.
16Àwọn ọ̀tá ti dáná sun ún, wọ́n ti gé e lulẹ̀;
fi ojú burúkú wò wọ́n, kí wọ́n ṣègbé!
17Ṣugbọn di ẹni tí o fúnra rẹ yàn mú,
àní, ọmọ eniyan, tí o fúnra rẹ sọ di alágbára.
18Ṣe bẹ́ẹ̀, a kò sì ní pada lẹ́yìn rẹ;
dá wa sí, a ó sì máa sìn ọ́!
19Mú wa bọ̀ sípò, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun!
Fi ojurere wò wá, kí á lè là!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 80: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀