Ọlọrun, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ti wọ inú ilẹ̀ ìní rẹ; wọ́n ti ba ilé mímọ́ rẹ jẹ́; wọ́n sì ti sọ Jerusalẹmu di ahoro. Wọ́n ti fi òkú àwọn iranṣẹ rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ; wọ́n sì ti sọ òkú àwọn eniyan mímọ́ rẹ di ìjẹ fún àwọn ẹranko ìgbẹ́. Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi, káàkiri Jerusalẹmu; kò sì sí ẹni tí yóo gbé wọn sin. A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa; àwọn tí ó yí wa ká ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n sì ń fi wá rẹ́rìn-ín. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí ayé ni o óo máa bínú ni? Àbí owú rẹ yóo máa jó bí iná? Tú ibinu rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́, ati orí àwọn ìjọba tí kò sìn ọ́. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run; wọ́n sì ti sọ ibùgbé rẹ di ahoro. Má gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa lára wa; yára, kí o ṣàánú wa, nítorí pé a ti rẹ̀ wá sílẹ̀ patapata. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa, nítorí iyì orúkọ rẹ; gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí orúkọ rẹ. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi máa sọ pé, “Níbo ni Ọlọrun wọn wà?” Níṣojú wa, gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ tí a pa lára àwọn orílẹ̀-èdè! Jẹ́ kí ìkérora àwọn ìgbèkùn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ; gẹ́gẹ́ bí agbára ńlá rẹ, dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sí. OLUWA, san ẹ̀san ẹ̀gàn tí àwọn aládùúgbò wa gàn ọ́, san án fún wọn ní ìlọ́po meje, Nígbà náà, àwa eniyan rẹ, àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ, yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae; a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.
Kà ORIN DAFIDI 79
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 79:1-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò