O. Daf 79:1-13
O. Daf 79:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌLỌRUN, awọn keferi wá si ilẹ-ini rẹ; tempili mimọ́ rẹ ni nwọn sọ di ẽri; nwọn sọ Jerusalemu di òkiti-alapa. Okú awọn iranṣẹ rẹ ni nwọn fi fun ẹiyẹ oju-ọrun li onjẹ, ẹran-ara awọn enia mimọ́ rẹ fun ẹranko ilẹ. Ẹ̀jẹ wọn ni nwọn ta silẹ bi omi yi Jerusalemu ka; kò si si ẹniti yio gbé wọn sìn. Awa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣuti si awọn ti o yi wa ka. Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o binu titi lailai? owú rẹ yio ha ma jó bi iná? Dà ibinu rẹ si ori awọn keferi ti kò mọ̀ ọ, ati si ori awọn ijọba ti kò kepè orukọ rẹ. Nitori ti nwọn ti mu Jakobu jẹ, nwọn si sọ ibujoko rẹ̀ di ahoro. Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ awọn aṣaju wa si wa: jẹ ki iyọnu rẹ ki o ṣaju wa nisisiyi: nitori ti a rẹ̀ wa silẹ gidigidi. Ràn wa lọwọ, Ọlọrun igbala wa, nitori ogo orukọ rẹ: ki o si gbà wa, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ wa nù, nitori orukọ rẹ. Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà? jẹ ki a mọ̀ igbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ ti a ta silẹ loju wa ninu awọn keferi. Jẹ ki imi-ẹdun onde nì ki o wá siwaju rẹ: gẹgẹ bi titobi agbara rẹ, iwọ dá awọn ti a yàn si pipa silẹ: Ki o si san ẹ̀gan wọn nigba meje fun awọn aladugbo wa li aiya wọn, nipa eyiti nwọn ngàn ọ, Oluwa. Bẹ̃li awa enia rẹ ati agutan papa rẹ, yio ma fi ọpẹ fun ọ lailai, awa o ma fi iyìn rẹ hàn lati irandiran.
O. Daf 79:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Ọlọrun, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ti wọ inú ilẹ̀ ìní rẹ; wọ́n ti ba ilé mímọ́ rẹ jẹ́; wọ́n sì ti sọ Jerusalẹmu di ahoro. Wọ́n ti fi òkú àwọn iranṣẹ rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run jẹ; wọ́n sì ti sọ òkú àwọn eniyan mímọ́ rẹ di ìjẹ fún àwọn ẹranko ìgbẹ́. Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ bí omi, káàkiri Jerusalẹmu; kò sì sí ẹni tí yóo gbé wọn sin. A ti di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa; àwọn tí ó yí wa ká ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n sì ń fi wá rẹ́rìn-ín. Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí ayé ni o óo máa bínú ni? Àbí owú rẹ yóo máa jó bí iná? Tú ibinu rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́, ati orí àwọn ìjọba tí kò sìn ọ́. Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run; wọ́n sì ti sọ ibùgbé rẹ di ahoro. Má gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wa lára wa; yára, kí o ṣàánú wa, nítorí pé a ti rẹ̀ wá sílẹ̀ patapata. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọrun Olùgbàlà wa, nítorí iyì orúkọ rẹ; gbà wá, sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí orúkọ rẹ. Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi máa sọ pé, “Níbo ni Ọlọrun wọn wà?” Níṣojú wa, gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ tí a pa lára àwọn orílẹ̀-èdè! Jẹ́ kí ìkérora àwọn ìgbèkùn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ; gẹ́gẹ́ bí agbára ńlá rẹ, dá àwọn tí a dájọ́ ikú fún sí. OLUWA, san ẹ̀san ẹ̀gàn tí àwọn aládùúgbò wa gàn ọ́, san án fún wọn ní ìlọ́po meje, Nígbà náà, àwa eniyan rẹ, àní, àwa agbo aguntan pápá rẹ, yóo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ títí lae; a óo sì máa sọ̀rọ̀ ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.
O. Daf 79:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ; wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́, wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà. Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ, ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀. Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi yí Jerusalẹmu ká, kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n. Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká, àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká. Nígbà wo, OLúWA? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé? Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná? Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀ rẹ, lórí àwọn ìjọba tí kò pe orúkọ rẹ; Nítorí wọ́n ti run Jakọbu wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro. Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa, nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi. Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa, fún ògo orúkọ rẹ; gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì nítorí orúkọ rẹ. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé, “Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?” Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde. Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ, gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú. San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ OLúWA. Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ, àti àgùntàn pápá rẹ, yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé; láti ìran dé ìran ni àwa ó fi ìyìn rẹ hàn.