O. Daf 79

79
Adura Ìdáǹdè Orílẹ̀-Èdè
1ỌLỌRUN, awọn keferi wá si ilẹ-ini rẹ; tempili mimọ́ rẹ ni nwọn sọ di ẽri; nwọn sọ Jerusalemu di òkiti-alapa.
2Okú awọn iranṣẹ rẹ ni nwọn fi fun ẹiyẹ oju-ọrun li onjẹ, ẹran-ara awọn enia mimọ́ rẹ fun ẹranko ilẹ.
3Ẹ̀jẹ wọn ni nwọn ta silẹ bi omi yi Jerusalemu ka; kò si si ẹniti yio gbé wọn sìn.
4Awa di ẹ̀gan si awọn aladugbo wa, ẹlẹya ati iyọṣuti si awọn ti o yi wa ka.
5Yio ti pẹ to, Oluwa? iwọ o binu titi lailai? owú rẹ yio ha ma jó bi iná?
6Dà ibinu rẹ si ori awọn keferi ti kò mọ̀ ọ, ati si ori awọn ijọba ti kò kepè orukọ rẹ.
7Nitori ti nwọn ti mu Jakobu jẹ, nwọn si sọ ibujoko rẹ̀ di ahoro.
8Máṣe ranti ẹ̀ṣẹ awọn aṣaju wa si wa: jẹ ki iyọnu rẹ ki o ṣaju wa nisisiyi: nitori ti a rẹ̀ wa silẹ gidigidi.
9Ràn wa lọwọ, Ọlọrun igbala wa, nitori ogo orukọ rẹ: ki o si gbà wa, ki o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ wa nù, nitori orukọ rẹ.
10Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà? jẹ ki a mọ̀ igbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ ti a ta silẹ loju wa ninu awọn keferi.
11Jẹ ki imi-ẹdun onde nì ki o wá siwaju rẹ: gẹgẹ bi titobi agbara rẹ, iwọ dá awọn ti a yàn si pipa silẹ:
12Ki o si san ẹ̀gan wọn nigba meje fun awọn aladugbo wa li aiya wọn, nipa eyiti nwọn ngàn ọ, Oluwa.
13Bẹ̃li awa enia rẹ ati agutan papa rẹ, yio ma fi ọpẹ fun ọ lailai, awa o ma fi iyìn rẹ hàn lati irandiran.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

O. Daf 79: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀