ORIN DAFIDI 78:65-72
ORIN DAFIDI 78:65-72 YCE
Lẹ́yìn náà, OLUWA dìde bí ẹni tají lójú oorun, bí ọkunrin alágbára tí ó mu ọtí yó tí ó ń kígbe. Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ sẹ́yìn; ó dójú tì wọ́n títí ayé. Ó kọ àgọ́ àwọn ọmọ Josẹfu sílẹ̀; kò sì yan ẹ̀yà Efuraimu; ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda, ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn. Níbẹ̀ ni ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀ tí ó ga bí ọ̀run sí, ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí ayé títí lae. Ó yan Dafidi iranṣẹ rẹ̀; ó sì mú un láti inú agbo ẹran. Ó mú un níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn aguntan tí ó lọ́mọ lẹ́yìn, kí ó lè máa tọ́jú àwọn ọmọ Jakọbu, eniyan rẹ̀, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan ìní rẹ̀. Ó tọ́jú wọn pẹlu òdodo, ó sì tọ́ wọn pẹlu ìmọ̀.

