O. Daf 78:65-72
O. Daf 78:65-72 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana li Oluwa ji bi ẹnipe loju orun, ati bi alagbara ti o nkọ nitori ọti-waini. O si kọlu awọn ọta rẹ̀ lẹhin; o sọ wọn di ẹ̀gan titi aiye. Pẹlupẹlu o kọ̀ agọ Josefu, kò si yàn ẹ̀ya Efraimu: Ṣugbọn o yan ẹ̀ya Juda, òke Sioni ti o fẹ. O si kọ́ ibi-mimọ́ rẹ̀ bi òke-ọrun bi ilẹ ti o ti fi idi rẹ̀ mulẹ lailai. O si yàn Dafidi iranṣẹ rẹ̀, o si mu u kuro lati inu agbo-agutan wá: Lati má tọ̀ awọn agutan lẹhin, ti o tobi fun oyun, o mu u lati ma bọ́ Jakobu, enia rẹ̀, ati Israeli, ilẹ-ini rẹ̀. Bẹ̃li o bọ́ wọn gẹgẹ bi ìwa-titọ inu rẹ̀; o si fi ọgbọ́n ọwọ rẹ̀ ṣe amọna wọn.
O. Daf 78:65-72 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, OLUWA dìde bí ẹni tají lójú oorun, bí ọkunrin alágbára tí ó mu ọtí yó tí ó ń kígbe. Ó lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ sẹ́yìn; ó dójú tì wọ́n títí ayé. Ó kọ àgọ́ àwọn ọmọ Josẹfu sílẹ̀; kò sì yan ẹ̀yà Efuraimu; ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda, ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn. Níbẹ̀ ni ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀ tí ó ga bí ọ̀run sí, ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ bí ayé títí lae. Ó yan Dafidi iranṣẹ rẹ̀; ó sì mú un láti inú agbo ẹran. Ó mú un níbi tí ó ti ń tọ́jú àwọn aguntan tí ó lọ́mọ lẹ́yìn, kí ó lè máa tọ́jú àwọn ọmọ Jakọbu, eniyan rẹ̀, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan ìní rẹ̀. Ó tọ́jú wọn pẹlu òdodo, ó sì tọ́ wọn pẹlu ìmọ̀.
O. Daf 78:65-72 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí. Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà; ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé. Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu, kò sì yan ẹ̀yà Efraimu, ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Juda, òkè Sioni, èyí tí ó fẹ́ràn. Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga, gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé. Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ ó mú láti inú àwọn agbo ẹran; Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu àti Israẹli ogún un rẹ̀. Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn; pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.