ORIN DAFIDI 78:2-6

ORIN DAFIDI 78:2-6 YCE

N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe; n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ, ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba ńlá wa ti sọ fún wa. A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn; a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn– iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe. Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu; ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa, pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn. Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n, àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí, kí àwọn náà ní ìgbà tiwọn lè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn.