O. Daf 78:2-6
O. Daf 78:2-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o ya ẹnu mi li owe: emi o sọ ọ̀rọ atijọ ti o ṣokunkun jade. Ti awa ti gbọ́, ti a si ti mọ̀, ti awọn baba wa si ti sọ fun wa. Awa kì yio pa wọn mọ́ kuro lọdọ awọn ọmọ wọn, ni fifi iyìn Oluwa, ati ipa rẹ̀, ati iṣẹ iyanu ti o ti ṣe hàn fun iran ti mbọ. Nitori ti o gbé ẹri kalẹ ni Jakobu, o si sọ ofin kan ni Israeli, ti o ti pa li aṣẹ fun awọn baba wa pe, ki nwọn ki o le sọ wọn di mimọ̀ fun awọn ọmọ wọn. Ki awọn iran ti mbọ̀ ki o le mọ̀, ani awọn ọmọ ti a o bi: ti yio si dide, ti yio si sọ fun awọn ọmọ wọn
O. Daf 78:2-6 Yoruba Bible (YCE)
N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe; n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ, ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba ńlá wa ti sọ fún wa. A kò ní fi pamọ́ fún àwọn ọmọ wọn; a óo máa sọ ọ́ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn– iṣẹ́ ńlá OLUWA ati ìṣe akọni rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe. Ó fi ìlànà lélẹ̀ fún ìdílé Jakọbu; ó gbé òfin kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa, pé kí wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn. Kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lè mọ̀ ọ́n, àní, àwọn ọmọ tí a kò tíì bí, kí àwọn náà ní ìgbà tiwọn lè sọ ọ́ fún àwọn ọmọ wọn.
O. Daf 78:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ó la ẹnu mi ní òwe, èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́; Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa. Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífi ìyìn OLúWA, àti ipa rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn