ORIN DAFIDI 6
6
Adura nígbà ìyọnu
1OLUWA, má fi ibinu bá mi wí;
má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà.
2Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí àárẹ̀ mú ọkàn mi,
OLUWA, wò mí sàn nítorí ara ń ni mí dé egungun.
3Ọkàn mi kò balẹ̀ rárá,
yóo ti pẹ́ tó, OLUWA, yóo ti pẹ́ tó?#O. Daf 38:1
4OLUWA, pada wá gbà mí,
gbà mí là nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
5Nítorí kò sí ẹni tí yóo ranti rẹ lẹ́yìn tí ó bá ti kú.
Àbí, ta ló lè yìn ọ́ ninu isà òkú?
6Ìkérora dá mi lágara:
ní òròòru ni mò ń fi omijé rẹ ẹní mi;
tí mò ń sunkún tí gbogbo ibùsùn mi ń tutù.
7Ìbànújẹ́ sọ ojú mi di bàìbàì,
agbára káká ni mo fi lè ríran nítorí ìnilára àwọn ọ̀tá.
8Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi,
nítorí OLUWA ti gbọ́ ìró ẹkún mi.
9OLUWA ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi,
OLUWA ti tẹ́wọ́gba adura mi.
10Ojú yóo ti gbogbo àwọn ọ̀tá mi;
ìdààmú ńlá yóo bá wọn,
wọn óo sá pada,
ojú yóo sì tì wọ́n lójijì.#Mat 7:23; Luk 13:27
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 6: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010