ORIN DAFIDI 44

44
Adura Ààbò
1Ọlọrun, a ti fi etí wa gbọ́,
àwọn baba wa sì ti sọ fún wa,
nípa àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,
àní, ní ayé àtijọ́:
2Ìwọ ni o fi ọwọ́ ara rẹ lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde fún wọn,
tí o sì fi ẹsẹ̀ àwọn baba wa múlẹ̀;
o fi ìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè náà,
o sì jẹ́ kí ó dára fún àwọn baba wa.
3Nítorí pé kì í ṣe idà wọn ni wọ́n fi gba ilẹ̀ náà,
kì í ṣe agbára wọn ni wọ́n fi ṣẹgun;
agbára rẹ ni; àní, agbára ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
ati ojurere rẹ;
nítorí pé inú rẹ dùn sí wọn.
4Ìwọ ni Ọba mi ati Ọlọrun mi;
ìwọ ni o fi àṣẹ sí i pé kí Jakọbu ó ṣẹgun.
5Nípa agbára rẹ ni a fi bi àwọn ọ̀tá wa sẹ́yìn,
orúkọ rẹ ni a fi tẹ àwọn tí ó gbógun tì wá mọ́lẹ̀.
6Nítorí pé kì í ṣe ọrun mi ni mo gbẹ́kẹ̀lé;
idà mi kò sì le gbà mí.
7Ṣugbọn ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,
o sì dójú ti àwọn tí ó kórìíra wa.
8Ìwọ Ọlọrun ni a fi ń yangàn nígbà gbogbo;
a óo sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí lae.
9Sibẹ, o ti ta wá nù o sì ti rẹ̀ wá sílẹ̀,
o ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde lọ sójú ogun mọ́.
10O ti mú kí á sá fún àwọn ọ̀tá wa lójú ogun;
àwọn tí ó kórìíra wa sì fi ẹrù wa ṣe ìkógun.
11O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà,
o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.
12O ti ta àwọn eniyan rẹ lọ́pọ̀,
o ò sì jẹ èrè kankan lórí wọn.
13O ti sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wa;
a di ẹni ẹ̀sín ati ẹni yẹ̀yẹ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ó yí wa ká.
14O sọ wá di ẹni àmúpòwe láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,
ati ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin gbogbo ayé.
15Àbùkù mi wà lára mi tọ̀sán-tòru,
ìtìjú sì ti bò mí.
16Ọ̀rọ̀ àwọn apẹ̀gàn ati apeni-níjà ṣẹ mọ́ mi lára,
lójú àwọn ọ̀tá mi ati àwọn tí ó fẹ́ gbẹ̀san.
17Gbogbo nǹkan yìí ló ṣẹlẹ̀ sí wa,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò gbàgbé rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹ majẹmu rẹ.
18Ọkàn wa kò pada lẹ́yìn rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni a kò yẹsẹ̀ kúrò ninu ìlànà rẹ,
19sibẹ o fọ́ wa túútúú fún ìjẹ àwọn ẹranko,
o sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.
20Bí ó bá jẹ́ pé a gbàgbé orúkọ Ọlọrun wa,
tabi tí a bá bọ oriṣa,
21ṣebí Ọlọrun ìbá ti mọ̀?
Nítorí òun ni olùmọ̀ràn ọkàn.
22Ṣugbọn nítorí tìrẹ ni wọ́n fi ń pa wá tọ̀sán-tòru,
tí a kà wá sí aguntan lọ́wọ́ alápatà.#Rom 8:36
23Para dà, OLUWA, kí ló dé tí o fi ń sùn?
Jí gìrì! Má ta wá nù títí lae.
24Kí ló dé tí o fi ń fi ojú pamọ́?
Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìpọ́njú ati ìnira wa?
25Nítorí pé àwọn ọ̀tá ti tẹ̀ wá mọ́lẹ̀;
àyà wa sì lẹ̀ mọ́lẹ̀ típẹ́típẹ́.
26Gbéra nílẹ̀, kí o ràn wá lọ́wọ́!
Gbà wá sílẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 44: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀