ORIN DAFIDI 42:5-11

ORIN DAFIDI 42:5-11 YCE

Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun, nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi, nítorí náà mo ranti rẹ láti òkè Herimoni, ati láti òkè Misari, wá sí agbègbè odò Jọdani, ìbànújẹ́ ń já lura wọn, ìdààmú sì ń dà gììrì, wọ́n bò mí mọ́lẹ̀ bí ìgbì omi òkun. Ní ọ̀sán, OLUWA fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn, ní òru, orin rẹ̀ gba ẹnu mi, àní, adura sí Ọlọrun ìyè mi. Mo bi Ọlọrun, àpáta mi pé, “Kí ló dé tí o fi gbàgbé mi? Kí ló dé tí mò ń ṣọ̀fọ̀ kiri nítorí ìnilára ọ̀tá?” Bí ọgbẹ́ aṣekúpani ni ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá mi rí lára mi, nígbà tí wọn ń bi mí lemọ́lemọ́ pé, “Níbo ni Ọlọrun rẹ wà?” Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.