ORIN DAFIDI 34:12-14

ORIN DAFIDI 34:12-14 YCE

Ta ni ń fẹ́ ìyè ninu yín, tí ń fẹ́ ẹ̀mí gígùn, tí ó fẹ́ pẹ́ láyé? Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú, ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde. Ẹ yàgò fún ibi, rere ni kí ẹ máa ṣe; ẹ máa wá alaafia, kí ẹ sì máa lépa rẹ̀.