ORIN DAFIDI 31:1-8

ORIN DAFIDI 31:1-8 YCE

OLUWA, ìwọ ni mo sá di, má jẹ́ kí ojú tì mí lae; gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́. Dẹ etí sí mi, yára gbà mí. Jẹ́ àpáta ààbò fún mi; àní ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là. Ìwọ ni àpáta ati ilé ààbò mi; nítorí orúkọ rẹ, máa tọ́ mi kí o sì máa fọ̀nà hàn mí. Yọ mí kúrò ninu àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ dè mí, nítorí ìwọ ni ẹni ìsádi mi. Ìwọ ni mo fi ẹ̀mí mi lé lọ́wọ́, o ti rà mí pada, OLUWA, Ọlọrun, olóòótọ́. Mo kórìíra àwọn tí ń bọ oriṣa lásánlàsàn, ṣugbọn OLUWA ni èmi gbẹ́kẹ̀lé. N óo máa yọ̀, inú mi óo sì máa dùn, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; nítorí pé o ti rí ìpọ́njú mi, o sì mọ ìṣòro mi. O ò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́, o sì ti fi ẹsẹ̀ mi lé ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.