O. Daf 31:1-8
O. Daf 31:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA, iwọ ni mo gbẹkẹ mi le: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi: gbà mi ninu ododo rẹ. Dẹ eti rẹ silẹ si mi: gbà mi nisisiyi: iwọ ma ṣe apata agbara mi, ile-ãbò lati gba mi si. Nitori iwọ li apata mi ati odi mi: nitorina nitori orukọ rẹ ma ṣe itọ́ mi, ki o si ma ṣe amọ̀na mi. Yọ mi jade ninu àwọn ti nwọn nà silẹ fun mi ni ìkọkọ: nitori iwọ li ãbo mi. Li ọwọ rẹ ni mo fi ẹmi mi le: iwọ li o ti rà mi pada, Oluwa Ọlọrun otitọ. Emi ti korira awọn ẹniti nfiyesi eke asan: ṣugbọn emi gbẹkẹle Oluwa. Emi o yọ̀, inu mi yio si dùn ninu ãnu rẹ: nitori ti iwọ ti rò ti iṣẹ́ mi; iwọ ti mọ̀ ọkàn mi ninu ipọnju; Iwọ kò si sé mi mọ́ si ọwọ ọta nì: iwọ fi ẹsẹ mi tẹlẹ ni ibi àye nla.
O. Daf 31:1-8 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, ìwọ ni mo sá di, má jẹ́ kí ojú tì mí lae; gbà mí, nítorí olóòótọ́ ni ọ́. Dẹ etí sí mi, yára gbà mí. Jẹ́ àpáta ààbò fún mi; àní ilé ààbò tó lágbára láti gbà mí là. Ìwọ ni àpáta ati ilé ààbò mi; nítorí orúkọ rẹ, máa tọ́ mi kí o sì máa fọ̀nà hàn mí. Yọ mí kúrò ninu àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ dè mí, nítorí ìwọ ni ẹni ìsádi mi. Ìwọ ni mo fi ẹ̀mí mi lé lọ́wọ́, o ti rà mí pada, OLUWA, Ọlọrun, olóòótọ́. Mo kórìíra àwọn tí ń bọ oriṣa lásánlàsàn, ṣugbọn OLUWA ni èmi gbẹ́kẹ̀lé. N óo máa yọ̀, inú mi óo sì máa dùn, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; nítorí pé o ti rí ìpọ́njú mi, o sì mọ ìṣòro mi. O ò fi mí lé ọ̀tá lọ́wọ́, o sì ti fi ẹsẹ̀ mi lé ilẹ̀ tí ó tẹ́jú.
O. Daf 31:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú rẹ̀, OLúWA ni mo ti rí ààbò; Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí; gbà mí nínú òdodo rẹ. Tẹ́ etí rẹ sí mi, gbà mí kíákíá; jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí. Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi. Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi, nítorí ìwọ ni ìsádi mi. Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé; ìwọ ni o ti rà mí padà, OLúWA, Ọlọ́run òtítọ́. Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí; ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé OLúWA. Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ, nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú. Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.