ORIN DAFIDI 27:1-14

ORIN DAFIDI 27:1-14 YCE

OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi; ta ni n óo bẹ̀rù? OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóo bà mí? Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi, tí wọ́n fẹ́ pa mí, àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi, wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú. Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí àyà mi kò ní já. Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi, sibẹ, ọkàn mi kò ní mì. Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA, òun ni n óo sì máa lépa: Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa wo ẹwà OLUWA, kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé, yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀, lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí; yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta. Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká; n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀, n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA. Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́; ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn. Nígbà tí o wí pé, “Ẹ máa wá ojú mi.” Ọkàn mi dá ọ lóhùn pé, “Ojú rẹ ni n óo máa wá, OLUWA, má fi ojú pamọ́ fún mi!” Má fi ibinu lé èmi iranṣẹ rẹ kúrò, ìwọ tí o ti ń ràn mí lọ́wọ́, má ta mí nù, má sì ṣá mi tì, Ọlọrun ìgbàlà mi. Bí baba ati ìyá mi tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀, OLUWA yóo tẹ́wọ́gbà mí. Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA, kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi. Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́; nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi, ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà. Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbà ní ilẹ̀ alààyè. Dúró de OLUWA, ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí, àní, dúró de OLUWA.

Verse Images for ORIN DAFIDI 27:1-14

ORIN DAFIDI 27:1-14 - OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi;
ta ni n óo bẹ̀rù?
OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi,
ẹ̀rù ta ni yóo bà mí?

Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi,
tí wọ́n fẹ́ pa mí,
àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi,
wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú.
Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí
àyà mi kò ní já.
Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi,
sibẹ, ọkàn mi kò ní mì.

Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA,
òun ni n óo sì máa lépa:
Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA
ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,
kí n lè máa wo ẹwà OLUWA,
kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀.
Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé,
yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀,
lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí;
yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta.
Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun
lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká;
n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀,
n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA.

Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́;
ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn.
Nígbà tí o wí pé, “Ẹ máa wá ojú mi.”
Ọkàn mi dá ọ lóhùn pé, “Ojú rẹ ni n óo máa wá, OLUWA,
má fi ojú pamọ́ fún mi!”

Má fi ibinu lé èmi iranṣẹ rẹ kúrò,
ìwọ tí o ti ń ràn mí lọ́wọ́,
má ta mí nù, má sì ṣá mi tì,
Ọlọrun ìgbàlà mi.
Bí baba ati ìyá mi tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀,
OLUWA yóo tẹ́wọ́gbà mí.
Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA,
kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ,
nítorí àwọn ọ̀tá mi.
Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́;
nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi,
ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà.

Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbà
ní ilẹ̀ alààyè.
Dúró de OLUWA,
ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí,
àní, dúró de OLUWA.ORIN DAFIDI 27:1-14 - OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi;
ta ni n óo bẹ̀rù?
OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi,
ẹ̀rù ta ni yóo bà mí?

Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi,
tí wọ́n fẹ́ pa mí,
àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi,
wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú.
Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí
àyà mi kò ní já.
Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi,
sibẹ, ọkàn mi kò ní mì.

Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA,
òun ni n óo sì máa lépa:
Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA
ní gbogbo ọjọ́ ayé mi,
kí n lè máa wo ẹwà OLUWA,
kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀.
Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé,
yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀,
lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí;
yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta.
Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun
lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká;
n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀,
n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA.

Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́;
ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn.
Nígbà tí o wí pé, “Ẹ máa wá ojú mi.”
Ọkàn mi dá ọ lóhùn pé, “Ojú rẹ ni n óo máa wá, OLUWA,
má fi ojú pamọ́ fún mi!”

Má fi ibinu lé èmi iranṣẹ rẹ kúrò,
ìwọ tí o ti ń ràn mí lọ́wọ́,
má ta mí nù, má sì ṣá mi tì,
Ọlọrun ìgbàlà mi.
Bí baba ati ìyá mi tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀,
OLUWA yóo tẹ́wọ́gbà mí.
Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA,
kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ,
nítorí àwọn ọ̀tá mi.
Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́;
nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi,
ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà.

Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbà
ní ilẹ̀ alààyè.
Dúró de OLUWA,
ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí,
àní, dúró de OLUWA.