O. Daf 27:1-14

O. Daf 27:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA ni imọlẹ mi ati igbala mi; tali emi o bẹ̀ru? Oluwa li agbara ẹmi mi; aiya tali yio fò mi? Nigbati awọn enia buburu, ani awọn ọta mi ati awọn abinuku mi sunmọ mi lati jẹ ẹran ara mi, nwọn kọsẹ, nwọn si ṣubu. Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le. Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ Oluwa, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile Oluwa li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà Oluwa, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tempili rẹ̀. Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata. Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa. Gbọ́, Oluwa, nigbati mo ba fi ohùn mi pè: ṣanu fun mi pẹlu, ki o si da mi li ohùn. Nigbati o wipe, Ẹ ma wa oju mi; ọkàn mi wi fun ọ pe, Oju rẹ, Oluwa, li emi o ma wá. Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi; máṣe fi ibinu ṣa iranṣẹ rẹ tì: iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi; má fi mi silẹ, bẹ̃ni ki o máṣe kọ̀ mi, Ọlọrun igbala mi. Nigbati baba ati iya mi kọ̀ mi silẹ, nigbana ni Oluwa yio tẹwọgbà mi. Kọ́ mi li ọ̀na rẹ, Oluwa, ki o si tọ́ mi li ọ̀na titọ, nitori awọn ọta mi. Máṣe fi mi le ifẹ awọn ọta mi lọwọ; nitori awọn ẹlẹri eke dide si mi, ati iru awọn ti nmí imí-ìkà. Ṣugbọn emi ti gbagbọ lati ri ire Oluwa ni ilẹ alãye. Duro de Oluwa; ki o si tújuka, yio si mu ọ li aiya le: mo ni, duro de Oluwa.

O. Daf 27:1-14 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ni ìmọ́lẹ̀ ati ìgbàlà mi; ta ni n óo bẹ̀rù? OLUWA ni ààbò ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóo bà mí? Nígbà tí àwọn aṣebi bá ń gbógun bọ̀ wá bá mi, tí wọ́n fẹ́ pa mí, àwọn alátakò ati àwọn ọ̀tá mi, wọn óo kọsẹ̀, wọn óo sì ṣubú. Bí ogun tilẹ̀ dó tì mí àyà mi kò ní já. Bí wọ́n tilẹ̀ gbé ogun wá bá mi, sibẹ, ọkàn mi kò ní mì. Ohun kan ni mo ti tọrọ lọ́dọ̀ OLUWA, òun ni n óo sì máa lépa: Kí n lè máa gbé inú ilé OLUWA ní gbogbo ọjọ́ ayé mi, kí n lè máa wo ẹwà OLUWA, kí n sì máa fi tọkàntọkàn sìn ín ninu tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé, nígbà tí ìpọ́njú bá dé, yóo fi mí pamọ́ sinu àgọ́ rẹ̀, lábẹ́ ààbò, ninu àgọ́ rẹ̀, ni yóo fi mí pamọ́ sí; yóo sì gbé mi sókè ka orí àpáta. Nisinsinyii n óo ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá mi tí ó yí mi ká; n óo rúbọ ninu àgọ́ rẹ̀ pẹlu ìhó ayọ̀, n óo sì kọ orin aládùn sí OLUWA. Gbọ́ OLUWA, nígbà tí mo bá ń kígbe pè ọ́; ṣàánú mi kí o sì dá mi lóhùn. Nígbà tí o wí pé, “Ẹ máa wá ojú mi.” Ọkàn mi dá ọ lóhùn pé, “Ojú rẹ ni n óo máa wá, OLUWA, má fi ojú pamọ́ fún mi!” Má fi ibinu lé èmi iranṣẹ rẹ kúrò, ìwọ tí o ti ń ràn mí lọ́wọ́, má ta mí nù, má sì ṣá mi tì, Ọlọrun ìgbàlà mi. Bí baba ati ìyá mi tilẹ̀ kọ̀ mí sílẹ̀, OLUWA yóo tẹ́wọ́gbà mí. Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLUWA, kí o sì tọ́ mi sí ọ̀nà títẹ́jú rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi. Má fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́; nítorí pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde sí mi, ètè wọn sì kún fún ọ̀rọ̀ ìkà. Mo gbàgbọ́ pé n óo rí oore OLUWA gbà ní ilẹ̀ alààyè. Dúró de OLUWA, ṣe bí akin, kí o sì mú ọkàn gírí, àní, dúró de OLUWA.

O. Daf 27:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi; ta ni èmi yóò bẹ̀rù? OLúWA ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi, ẹ̀rù ta ni yóò bà mí? Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi láti jẹ ẹran-ara mi, àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi, wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú. Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi, ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù; bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi, nínú èyí ni ọkàn mi yóò le. Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ OLúWA, òhun ni èmi yóò máa wá kiri: kí èmi kí ó le wà ní ilé OLúWA ní ọjọ́ ayé mi gbogbo, kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà OLúWA, kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀. Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀; níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́; yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta. Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká; èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀; èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí OLúWA. Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! OLúWA, ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn; “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.” Ojú rẹ, OLúWA, ni èmí ń wá. Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi, má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì; ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi, Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí, háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi. Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀, OLúWA yóò tẹ́wọ́ gbà mí. Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, OLúWA, kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú nítorí àwọn ọ̀tá mi. Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́, nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi, wọ́n sì mí ìmí ìkà. Èmi ní ìgbàgbọ́ pé, èmi yóò rí ìre OLúWA ní ilẹ̀ alààyè. Dúró de OLúWA; kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le àní dúró de OLúWA.

O. Daf 27:1-14

O. Daf 27:1-14 YBCVO. Daf 27:1-14 YBCV