ORIN DAFIDI 25:14-17

ORIN DAFIDI 25:14-17 YCE

Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́, a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n. OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo, nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n. Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi; nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi. Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò; kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ORIN DAFIDI 25:14-17