O. Daf 25:14-17
O. Daf 25:14-17 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́, a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n. OLUWA ni mò ń wò lójú nígbà gbogbo, nítorí òun ni yóo yọ ẹsẹ̀ mi kúrò ninu àwọ̀n. Kọjú sí mi kí o sì ṣàánú mi; nítorí n kò lẹ́nìkan, ojú sì ń pọ́n mi. Mú ìdààmú ọkàn mi kúrò; kí o sì yọ mí ninu gbogbo ìpọ́njú mi.
O. Daf 25:14-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn. Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ OLúWA, nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà. Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi; nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú. Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
O. Daf 25:14-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Aṣiri Oluwa wà pẹlu awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, yio si fi wọn mọ̀ majẹmu rẹ̀. Oju mi gbé soke si Oluwa lai; nitori ti yio fà ẹsẹ mi yọ kuro ninu àwọn na. Yipada si mi, ki o si ṣãnu fun mi; nitori ti mo di ofo, mo si di olupọnju. Iṣẹ́ aiya mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi.