OLUWA ló ni ilẹ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀, òun ló ni ayé, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀; nítorí pé òun ló fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí òkun, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí ìṣàn omi. Ta ló lè gun orí òkè OLUWA lọ? Ta ló sì lè dúró ninu ibi mímọ́ rẹ̀? Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ mọ́, tí inú rẹ̀ sì funfun, tí kò gbẹ́kẹ̀lé oriṣa lásánlàsàn, tí kò sì búra èké. Òun ni yóo rí ibukun gbà lọ́dọ̀ OLUWA, tí yóo sì rí ìdáláre gbà lọ́wọ́ Ọlọrun, Olùgbàlà rẹ̀. Irú wọn ni àwọn tí ń wá OLUWA, àní àwọn tí ń wá ojurere Ọlọrun Jakọbu.
Kà ORIN DAFIDI 24
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 24:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò