Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye; ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru. Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo, nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀. Nítorí náà ni ọkàn mi ṣe ń yọ̀, tí inú mi dùn; ara sì rọ̀ mí. Nítorí o kò ní gbàgbé mi sí ipò òkú, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni tí ó fi tọkàntọkàn sìn ọ́ rí ìdíbàjẹ́. O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí; ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ, ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
Kà ORIN DAFIDI 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ORIN DAFIDI 16:7-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò