ORIN DAFIDI 149

149
Orin Ìyìn sí OLUWA
1Ẹ yin OLUWA!
Ẹ kọ orin titun sí OLUWA,
ẹ kọrin ìyìn sí i ninu àwùjọ àwọn olóòótọ́.
2Kí Israẹli máa yọ̀ ninu Ẹlẹ́dàá rẹ̀,
kí àwọn ọmọ Sioni máa fò fún ayọ̀ pé àwọn ní Ọba.
3Kí wọn máa fi ijó yin orúkọ rẹ̀,
kí wọn máa fi ìlù ati hapu kọ orin aládùn sí i.
4Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀,
a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.
5Kí àwọn olódodo máa ṣògo ninu ọlá;
kí wọ́n máa kọrin ayọ̀ lórí ibùsùn wọn.
6Kí wọn máa fi ohùn wọn yin Ọlọrun;
kí idà olójú meji sì wà ní ọwọ́ wọn,
7láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,
ati láti jẹ àwọn eniyan wọn níyà;
8láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn,
ati láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn ọlọ́lá wọn;
9láti ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀.
Ògo gbogbo àwọn olódodo nìyí.#2 Makab 15:27
Ẹ yin OLUWA!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 149: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀