ORIN DAFIDI 142
142
Adura Ìrànlọ́wọ́#1Sam 22:1; 24:3
1Mo ké pe OLUWA,
mo gbé ohùn ẹ̀bẹ̀ sókè sí i.
2Mo tú ẹ̀dùn ọkàn mi palẹ̀ níwájú rẹ̀,
mo sọ ìṣòro mi fún un.
3Nígbà tí ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì,
ó mọ ọ̀nà tí mo lè gbà.
Wọ́n ti dẹ tàkúté sílẹ̀ fún mi
ní ọ̀nà tí mò ń rìn.
4Mo wo ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún mi yíká,
mo rí i pé kò sí ẹni tí ó náání mi;
kò sí ààbò fún mi,
ẹnikẹ́ni kò sì bìkítà fún mi.
5Mo ké pè ọ́, OLUWA,
mo ní, “Ìwọ ni ààbò mi,
ìwọ ni ìpín mi lórí ilẹ̀ alààyè.”
6Gbọ́ igbe mi;
nítorí wọ́n ti rẹ̀ mí sílẹ̀ patapata.
Gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi,
nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
7Yọ mí kúrò ninu ìhámọ́,
kí n lè yin orúkọ rẹ lógo.
Àwọn olódodo yóo yí mi ká,
nítorí ọpọlọpọ oore tí o óo ṣe fún mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 142: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010