ORIN DAFIDI 141
141
Adura Ààbò
1OLUWA, mo ké pè ọ́, tètè wá dá mi lóhùn,
tẹ́tí sí ohùn mi nígbà tí mo bá ń ké pè ọ́.
2Jẹ́ kí adura mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ bíi turari,
sì jẹ́ kí ọwọ́ adura tí mo gbé sókè dàbí ẹbọ àṣáálẹ́. #Ifi 5:8
3OLUWA, fi ìjánu sí mi ní ẹnu,
sì ṣe aṣọ́nà ètè mi.
4Má jẹ́ kí ọkàn mi fà sí ibi, má sì jẹ́ kí n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìkà.
Má jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rìn pọ̀,
má sì jẹ́ kí n jẹ ninu oúnjẹ àdídùn wọn.
5N ò kọ̀ kí ẹni rere bá mi wí,
n ò kọ̀ kí ó nà mí;
kí ó ṣá ti fi ìfẹ́ bá mi wí.
Ṣugbọn má jẹ́ kí eniyan burúkú tilẹ̀ ta òróró sí mi lórí,
nítorí pé nígbàkúùgbà ni mò ń fi adura tako ìwà ibi wọn.
6Nígbà tí ọwọ́ àwọn tí yóo dá wọn lẹ́bi bá tẹ̀ wọ́n,
wọn óo gbà pé, òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA.
7Bí òkúta tí eniyan là, tí ó fọ́ yángá-yángá sílẹ̀,
ni a óo fọ́n egungun wọn ká sí ẹnu ibojì.
8Ṣugbọn ìwọ ni mo gbójúlé, OLUWA, Ọlọrun.
Ìwọ ni asà mi,
má fi mí sílẹ̀ láìní ààbò.
9Pa mí mọ́ ninu ewu tàkúté,
ati ti okùn tí àwọn aṣebi dẹ sílẹ̀ dè mí.
10Jẹ́ kí àwọn eniyan burúkú ṣubú sinu àwọ̀n ara wọn,
kí èmi sì lọ láìfarapa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 141: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010