ORIN DAFIDI 132

132
Majẹmu Ọlọrun pẹlu Ìdílé Dafidi
1OLUWA, ranti gbogbo ìyà tí Dafidi fara dà.
2Ranti bí ó ṣe búra fún OLUWA,
tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu,
3tí ó ní, “N kò ní wọ inú ilé mi,
bẹ́ẹ̀ ni n kò ní bọ́ sí orí ibùsùn mi;
4n kò ní sùn,
bẹ́ẹ̀ ni n kò ní tòògbé,
5títí tí n óo fi wá ààyè fún OLUWA,
àní, tí n óo fi pèsè ibùgbé fún ìwọ Alágbára, Ọlọrun Jakọbu.”
6A gbúròó rẹ̀ ní Efurata,
a rí i ní oko Jearimu.
7“Ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùgbé rẹ̀;
ẹ jẹ́ kí á lọ wólẹ̀ níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.”
8Dìde, OLUWA, lọ sí ibi ìsinmi rẹ,
tìwọ ti àpótí agbára rẹ.
9Jẹ́ kí àwọn alufaa rẹ wọ ẹ̀wù òdodo,
kí àwọn eniyan mímọ́ rẹ sì máa kọrin ayọ̀.
10Nítorí ti Dafidi, iranṣẹ rẹ,
má jẹ́ kí ẹni tí a fi òróró rẹ yàn yíjú kúrò lára rẹ.
11OLUWA ti ṣe ìbúra tí ó dájú fún Dafidi,
èyí tí kò ní yipada; ó ní,
“Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ
ni n óo gbé ka orí ìtẹ́ rẹ.
12Bí àwọn ọmọ rẹ bá pa majẹmu mi mọ́,
tí wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí n óo fi lélẹ̀ fún wọn,
àwọn ọmọ tiwọn náà óo jókòó lórí ìtẹ́ rẹ títí lae.”
13Nítorí OLUWA ti yan Sioni;
ó fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀:
14Ó ní, “Ìhín ni ibi ìsinmi mi títí lae,
níhìn-ín ni n óo máa gbé, nítorí pé ó wù mí.
15N óo bù sí oúnjẹ rẹ̀ lọpọlọpọ;
n óo fi oúnjẹ tẹ́ àwọn aláìní ibẹ̀ lọ́rùn.
16N óo gbé ẹ̀wù ìgbàlà wọ àwọn alufaa rẹ̀,
àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀ yóo sì kọrin ayọ̀.
17Níbẹ̀ ni n óo ti fún Dafidi ní agbára;
mo ti gbé àtùpà kalẹ̀ fún ẹni tí mo fi òróró yàn.
18N óo da ìtìjú bo àwọn ọ̀tá rẹ̀ bí aṣọ,
ṣugbọn adé orí rẹ̀ yóo máa tàn yinrinyinrin.”#2Kron 6:41-42 #2Sam 7:12-16; 1Kron 17:11-14; O. Daf 89:3-4; A. Apo 2:30 #1A. Ọba 11:36

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 132: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀