OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ,
n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin.
Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,
kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́.
Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ,
nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀.
Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ,
kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé.
Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán,
sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ.
Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ,
àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ.
Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò,
nítorí pé ìlànà rẹ dára.
Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ,
sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ!
Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA,
kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn,
nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá,
nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ.
N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae.
N óo máa rìn fàlàlà,
nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ.
N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba,
ojú kò sì ní tì mí.
Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ,
nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀.
Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn,
n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.
Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ,
èyí tí ó fún mi ní ìrètí.
Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:
ìlérí rẹ mú mi wà láàyè.
Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,
ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀.
Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,
OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.
Inú mi á máa ru,
nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,
tí wọn ń rú òfin rẹ.
Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,
lákòókò ìrìn àjò mi láyé.
Mo ranti orúkọ rẹ lóru;
OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́:
Èyí ni ìṣe mi:
Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́.
OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní;
mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́.
Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ,
ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi,
mo yipada sí ìlànà rẹ;
mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́.
Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi,
n kò ní gbàgbé òfin rẹ.
Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́,
nítorí ìlànà òdodo rẹ.
Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí,
àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́.
OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ,
gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé,
nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ.
Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ;
ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ.
OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀,
ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́.
Ọkàn wọn ti yigbì,
ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ.
Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani,
ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ.
Òfin rẹ níye lórí fún mi,
ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.