O. Daf 119:33-72
O. Daf 119:33-72 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọ́ mi, OLúWA, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin. Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi. Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí, nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn. Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́. Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí òfin rẹ dára. Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára. Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ! Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, OLúWA, ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ; Nígbà náà ni èmi yóò dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn, nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé. Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira, nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde. Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí, Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn. Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn, èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀. Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí. Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí: ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́. Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró, ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ. Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, OLúWA, èmi sì rí ìtùnú nínú wọn. Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú, tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀. Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi níbikíbi tí èmi ń gbé. Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, OLúWA, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ nítorí tí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́. Ìwọ ni ìpín mi, OLúWA: èmi ti pinnu láti tẹríba sí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi ti wá ojú rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi: fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Èmi ti kíyèsi ọ̀nà mi èmi sì ti gbé ìgbésẹ̀ mi sí òfin rẹ. Èmi yóò yára, ń kò ni lọ́ra láti gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹni búburú dì mí pẹ̀lú okùn, èmi kò ní gbàgbé òfin rẹ. Ní àárín ọ̀gànjọ́ òru èmi dìde láti fi ọpẹ́ fún ọ nítorí òfin òdodo rẹ. Èmi jẹ́ ọ̀rẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ, sí gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé ẹ̀kọ́ rẹ. Ayé kún fún ìfẹ́ rẹ OLúWA Kọ́ mi ní òfin rẹ. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, OLúWA. Kọ́ mi ní ìmọ̀ àti ìdájọ́ rere, nítorí mo gbàgbọ́ nínú àṣẹ rẹ. Kí a tó pọ́n mi lójú èmi ti ṣìnà, ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí èmi gbọ́rọ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ. Ìwọ dára, ohun tí ìwọ sì ń ṣe rere ni; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbéraga ti gbìmọ̀ èké sí mí, èmi pa ẹ̀kọ́ rẹ mọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi. Ọkàn wọn yigbì kò sì ní àánú, ṣùgbọ́n èmi ní inú dídùn nínú òfin rẹ. Ó dára fún mi kí a pọ́n mi lójú nítorí kí èmi lè kọ́ òfin rẹ. Òfin tí ó jáde láti ẹnu rẹ ju iyebíye sí mi lọ ó ju ẹgbẹ̀rún ẹyọ fàdákà àti wúrà lọ.
O. Daf 119:33-72 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin. Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo. Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi. Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro. Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ. Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀. Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara. Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ. Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ. Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ. Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai. Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ. Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju. Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ. Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ. Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti. Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye. Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ. Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu. Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ. Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi. Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́. Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́. Oluwa, iwọ ni ipin mi: emi ti wipe, emi o pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Emi ti mbẹ̀bẹ oju-rere rẹ tinutinu mi gbogbo: ṣãnu fun mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi rò ọ̀na mi, mo si yi ẹsẹ mi pada si ẹri rẹ. Emi yara, emi kò si lọra lati pa ofin rẹ mọ́. Okùn awọn enia buburu ti yi mi ka: ṣugbọn emi kò gbagbe ofin rẹ. Lãrin ọganjọ emi o dide lati dupẹ fun ọ nitori ododo idajọ rẹ. Ẹgbẹ gbogbo awọn ti o bẹ̀ru rẹ li emi, ati ti awọn ti npa ẹkọ́ rẹ mọ́. Oluwa, aiye kún fun ãnu rẹ: kọ́ mi ni ilana rẹ. Iwọ ti nṣe rere fun iranṣẹ rẹ Oluwa, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Kọ́ mi ni ìwa ati ìmọ̀ rere; nitori ti mo gbà aṣẹ rẹ gbọ́. Ki a to pọ́n mi loju emi ti ṣina: ṣugbọn nisisiyi emi ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Iwọ ṣeun iwọ si nṣe rere; kọ́ mi ni ilana rẹ. Awọn agberaga ti hùmọ eke si mi: ṣugbọn emi o pa ẹkọ́ rẹ mọ́ tinutinu mi gbogbo. Aiya wọn sebọ bi ọrá; ṣugbọn emi o ṣe inu-didùn ninu ofin rẹ. O dara fun mi ti a pọ́n mi loju; ki emi ki o le kọ́ ilana rẹ. Ofin ẹnu rẹ dara fun mi jù ẹgbẹgbẹrun wura ati fadaka lọ.

O. Daf 119:33-72 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ, n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin. Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́, kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́. Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ, nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀. Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ, kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé. Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán, sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ. Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ, àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ. Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò, nítorí pé ìlànà rẹ dára. Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ, sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ! Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn, nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ. Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá, nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ. N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae. N óo máa rìn fàlàlà, nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ. N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba, ojú kò sì ní tì mí. Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ, nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀. Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn, n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ. Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ, èyí tí ó fún mi ní ìrètí. Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé: ìlérí rẹ mú mi wà láàyè. Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi, ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀. Mo ranti òfin rẹ àtijọ́, OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀. Inú mi á máa ru, nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú, tí wọn ń rú òfin rẹ. Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ, lákòókò ìrìn àjò mi láyé. Mo ranti orúkọ rẹ lóru; OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́: Èyí ni ìṣe mi: Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ìwọ nìkan ni mo ní; mo ṣe ìlérí láti pa òfin rẹ mọ́. Tọkàntọkàn ni mò ń wá ojurere rẹ, ṣe mí lóore gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Nígbà tí mo ronú nípa ìṣe mi, mo yipada sí ìlànà rẹ; mo yára, bẹ́ẹ̀ ni n kò lọ́ra láti pa òfin rẹ mọ́. Bí okùn àwọn eniyan burúkú tilẹ̀ wé mọ́ mi, n kò ní gbàgbé òfin rẹ. Mo dìde lọ́gànjọ́ láti yìn ọ́, nítorí ìlànà òdodo rẹ. Ọ̀rẹ́ gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ ni mí, àní, àwọn tí wọn ń pa òfin rẹ mọ́. OLUWA, ayé kún fún ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. OLUWA, o ti ṣeun fún èmi iranṣẹ rẹ, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Fún mi ní òye ati ìmọ̀ pípé, nítorí mo ní igbagbọ ninu àṣẹ rẹ. Kí o tó jẹ mí níyà, mo yapa kúrò ninu òfin rẹ; ṣugbọn nisinsinyii, mò ń mú àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA rere ni ọ́, rere ni o sì ń ṣe; kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Àwọn onigbeeraga ti wé irọ́ mọ́ mi lẹ́sẹ̀, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́. Ọkàn wọn ti yigbì, ṣugbọn èmi láyọ̀ ninu òfin rẹ. Ìpọ́njú tí mo rí ṣe mí ní anfaani, ó mú kí n kọ́ nípa ìlànà rẹ. Òfin rẹ níye lórí fún mi, ó ju ẹgbẹẹgbẹrun wúrà ati fadaka lọ.