ORIN DAFIDI 118:19-29

ORIN DAFIDI 118:19-29 YCE

Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi, kí n lè gba ibẹ̀ wọlé, kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA. Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA; àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi, o sì ti di olùgbàlà mi. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, ni ó di pataki igun ilé. OLUWA ló ṣe èyí; ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa. Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá, ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn. OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá, OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA, láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA. OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa. Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà, títí dé ibi ìwo pẹpẹ. Ìwọ ni Ọlọrun mi, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ. Ìwọ ni Ọlọrun mi, n óo máa gbé ọ ga. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.