O. Daf 118:19-29
O. Daf 118:19-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ododo silẹ fun mi: emi o ba ibẹ wọle, emi o ma yìn Oluwa. Eyi li ẹnu-ọ̀na Oluwa, ti awọn olododo yio ba wọle. Emi o yìn ọ: nitori ti iwọ gbohùn mi, iwọ si di igbala mi. Okuta ti awọn ọ̀mọle kọ̀ silẹ li o di pataki igun ile. Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa. Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀. Ṣe igbala nisisiyi, emi mbẹ ọ, Oluwa: Oluwa emi bẹ ọ, rán alafia. Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: awa ti fi ibukún fun ọ lati ile Oluwa wá. Ọlọrun li Oluwa, ti o ti fi imọlẹ hàn fun wa: ẹ fi okùn di ẹbọ na mọ́ iwo pẹpẹ na. Iwọ li Ọlọrun mi, emi o si ma yìn ọ, iwọ li Ọlọrun mi, emi o mã gbé ọ ga. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
O. Daf 118:19-29 Yoruba Bible (YCE)
Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi, kí n lè gba ibẹ̀ wọlé, kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA. Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA; àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi, o sì ti di olùgbàlà mi. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, ni ó di pataki igun ilé. OLUWA ló ṣe èyí; ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa. Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá, ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn. OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá, OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA, láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA. OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa. Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà, títí dé ibi ìwo pẹpẹ. Ìwọ ni Ọlọrun mi, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ. Ìwọ ni Ọlọrun mi, n óo máa gbé ọ ga. Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
O. Daf 118:19-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òdodo fún mi: èmi yóò bá ibẹ̀ wọlé, èmi yóò sì fi ọpẹ́ fún OLúWA. Èyí ni ìlẹ̀kùn OLúWA ibẹ̀ ni àwọn olódodo yóò bá wọlé. Èmi yóò fi ọpẹ́ fún ọ, nítorí ó dá mi lóhùn; ìwọ sì di ìgbàlà mi. Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, ni ó di pàtàkì igun ilé; OLúWA ti ṣe èyí, ó ṣe ìyanu ní ojú wa. Èyí ni ọjọ́ tí OLúWA dá: ẹ jẹ́ kí ayọ̀ kí inú wa sì máa dùn nínú rẹ̀. OLúWA, gbà wá; OLúWA, fún wa ní àlàáfíà. Ìbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLúWA. Àwa ti fi ìbùkún fún ọ láti ilé OLúWA wá. OLúWA ni Ọlọ́run, ó ti mú ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tàn sí wa lára pẹ̀lú ẹ̀ka igi ní ọwọ́, ó dára pọ̀ mọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń wọ́ nínú ayọ̀ ẹ fi okùn di ẹbọ náà mọ́ ìwo pẹpẹ. Ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ; ìwọ ni Ọlọ́run mi, èmi yóò gbé ọ ga. Ẹ fi ọpẹ́ fún OLúWA, nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.