ORIN DAFIDI 116

116
Orin Ọpẹ́
1Mo fẹ́ràn OLUWA nítorí pé ó gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ mi.
2Nítorí pé ó tẹ́tí sí mi,
nítorí náà, n óo máa ké pè é
níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè.
3Tàkúté ikú yí mi ká;
ìrora isà òkú dé bá mi;
ìyọnu ati ìnira sì bò mí mọ́lẹ̀.
4Nígbà náà ni mo ké pe OLUWA,
mo ní, “OLUWA, mo bẹ̀ ọ́, gbà mí!”
5Olóore ọ̀fẹ́ ati olódodo ni OLUWA,
aláàánú ni Ọlọrun wa.
6OLUWA a máa pa àwọn onírẹ̀lẹ̀ mọ́;
nígbà tí a rẹ̀ mí sílẹ̀, ó gbà mí.
7Sinmi ìwọ ọkàn mi, bíi ti àtẹ̀yìnwá,
nítorí pé OLUWA ṣeun fún ọ lọpọlọpọ.
8Nítorí ìwọ OLUWA ti gba ọkàn mi lọ́wọ́ ikú,
o gba ojú mi lọ́wọ́ omijé,
o sì gba ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú.
9Mò ń rìn níwájú OLUWA, lórí ilẹ̀ alààyè.
10Igbagbọ mi kò yẹ̀, nígbà tí mo tilẹ̀ wí pé,
“Ìpọ́njú dé bá mi gidigidi.”#2Kọr 4:13
11Mo wí ninu ìdààmú ọkàn pé,
“Èké ni gbogbo eniyan.”
12Kí ni n óo san fún OLUWA,
nítorí gbogbo oore rẹ̀ lórí mi?
13N óo mu ẹbọ nǹkan mímu wá fún OLUWA,
n óo sì pe orúkọ rẹ̀.
14N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA,
lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀.
15Iyebíye ni ikú àwọn eniyan rẹ̀ mímọ́ lójú OLUWA.
16OLUWA, iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́,
iranṣẹ rẹ ni mo jẹ́, àní, ọmọ iranṣẹbinrin rẹ.
O ti tú ìdè mi.
17N óo rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ,
n óo sì pe orúkọ rẹ OLUWA.
18N óo san ẹ̀jẹ́ mi fún OLUWA
lójú gbogbo àwọn eniyan rẹ̀,
19ninu àgbàlá ilé OLUWA,
láàrin rẹ, ìwọ ìlú Jerusalẹmu.
Ẹ máa yin OLUWA!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 116: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀