ORIN DAFIDI 109:1-4

ORIN DAFIDI 109:1-4 YCE

Má dákẹ́, ìwọ Ọlọrun tí mò ń yìn. Nítorí pé ẹnu àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn ẹlẹ́tàn kò dákẹ́, wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké nípa mi. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ káàkiri nípa mi, wọ́n sì ń gbógun tì mí láìnídìí. Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí, sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn.