O. Daf 109:1-4
O. Daf 109:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Má dákẹ́, ìwọ Ọlọrun tí mò ń yìn. Nítorí pé ẹnu àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn ẹlẹ́tàn kò dákẹ́, wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké nípa mi. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ káàkiri nípa mi, wọ́n sì ń gbógun tì mí láìnídìí. Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí, sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn.
O. Daf 109:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
MÁṢE pa ẹnu rẹ mọ́, Ọlọrun iyìn mi; Nitori ti ẹnu awọn enia buburu, ati ẹnu awọn ẹlẹtan yà silẹ si mi: nwọn ti fi ahọn eke sọ̀rọ si mi. Nwọn si fi ọ̀rọ irira yi mi ka kiri; nwọn si mba mi ja li ainidi. Nipo ifẹ mi nwọn nṣe ọta mi: ṣugbọn emi ngba adura.
O. Daf 109:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Má dákẹ́, ìwọ Ọlọrun tí mò ń yìn. Nítorí pé ẹnu àwọn eniyan burúkú ati ti àwọn ẹlẹ́tàn kò dákẹ́, wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké nípa mi. Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ káàkiri nípa mi, wọ́n sì ń gbógun tì mí láìnídìí. Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí, sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn.
O. Daf 109:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún Má ṣe dákẹ́ Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn ti ya ẹnu wọn sí mi wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri; wọ́n bá mi jà láìnídìí Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi, ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.