ORIN DAFIDI 108:1-13

ORIN DAFIDI 108:1-13 YCE

Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun ọkàn mi dúró ṣinṣin. N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. Jí, ìwọ ọkàn mi! Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu! Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan, n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun, kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé. Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là, fi ọwọ́ agbára rẹ gbà wá, kí o sì dá mi lóhùn. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀, ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu, n óo sì pín àfonífojì Sukotu. Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase. Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi. Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé, n óo sì hó ìhó ìṣẹ́gun lórí Filistia.” Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà? Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu? Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀? Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa lọ sójú ogun mọ́. Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan. Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a óo ṣe akin; nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.