O. Daf 108:1-13
O. Daf 108:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLỌRUN, ọkàn mi ti mura, emi o ma kọrin, emi o si ma fi ogo mi kọrin iyìn. Ji, ohun-elo orin mimọ́ ati dùrù: emi tikarami yio si ji ni kutukutu. Emi o ma yìn ọ, Oluwa, ninu awọn enia: emi o mã kọrin si ọ ninu awọn orilẹ-ède. Nitori ti ãnu rẹ tobi jù ọrun lọ: ati otitọ rẹ titi de awọsanma. Gbé ara rẹ ga, Ọlọrun, lori awọn ọrun: ati ogo rẹ lori gbogbo aiye. Ki a le gbà awọn olufẹ rẹ là: fi ọwọ ọtún rẹ ṣe igbala, ki o si da mi lohùn. Ọlọrun ti sọ̀rọ ninu ìwa-mimọ́ rẹ̀ pe; Emi o yọ̀, emi o pin Ṣekemu, emi o si wọ̀n afonifoji Sukkotu. Ti emi ni Gileadi: ti emi ni Manasse: Efraimu pẹlu li agbara ori mi: Juda li olofin mi: Moabu ni ikoko-iwẹsẹ mi; lori Edomu li emi o bọ́ bata mi si; lori Filistia li emi o ho iho-ayọ̀. Tani yio mu mi wá sinu ilu olodi ni? tani yio sìn mi lọ si Edomu? Iwọ Ọlọrun ha kọ́, ẹniti o ti ṣa wa tì? Ọlọrun, iwọ kì yio si ba awọn ogun wa jade lọ? Fun wa ni iranlọwọ ninu ipọnju: nitori asan ni iranlọwọ enia. Nipasẹ Ọlọrun li awa o ṣe akin; nitori on ni yio tẹ̀ awọn ọta wa mọlẹ.
O. Daf 108:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Ọkàn mi dúró ṣinṣin, Ọlọrun ọkàn mi dúró ṣinṣin. N óo kọrin, n óo sì máa yìn ọ́. Jí, ìwọ ọkàn mi! Ẹ jí ẹ̀yin ohun èlò ìkọrin ati hapu! Èmi fúnra mi náà yóo jí ní òwúrọ̀ kutukutu, OLUWA, n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ láàrin àwọn eniyan, n óo sì máa kọrin ìyìn sí ọ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run. Kí á gbé ọ ga ju ọ̀run lọ, Ọlọrun, kí ògo rẹ sì kárí gbogbo ayé. Kí á lè gba àyànfẹ́ rẹ là, fi ọwọ́ agbára rẹ gbà wá, kí o sì dá mi lóhùn. Ọlọrun ti sọ̀rọ̀ ninu ilé mímọ́ rẹ̀, ó ní, “Tayọ̀tayọ̀ ni n óo fi pín Ṣekemu, n óo sì pín àfonífojì Sukotu. Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase. Efuraimu ni àkẹtẹ̀ àṣíborí mi, Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi. Moabu ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ni n óo bọ́ bàtà mi lé, n óo sì hó ìhó ìṣẹ́gun lórí Filistia.” Ta ni yóo mú mi wọ inú ìlú olódi náà? Ta ni yóo mú mi lọ sí Edomu? Ọlọrun, o kò ha ti kọ̀ wá sílẹ̀? Ọlọrun, o ò bá àwọn ọmọ ogun wa lọ sójú ogun mọ́. Ràn wá lọ́wọ́, bá wa gbógun ti àwọn ọ̀tá wa, nítorí pé asán ni ìrànlọ́wọ́ eniyan. Pẹlu àtìlẹ́yìn Ọlọ́run, a óo ṣe akin; nítorí òun ni yóo tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.
O. Daf 108:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin. Jí ohun èlò orin àti haapu! Èmi ó jí ní kùtùkùtù, èmi ó yìn ọ́, OLúWA, nínú àwọn orílẹ̀-èdè, èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn. Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀. Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé. Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là; fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà, kí o sì dá mi lóhùn Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu, èmi yóò sì wọn àfonífojì Sukkoti kúrò. Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi, Efraimu ni ìbòrí mi, Juda ni olófin mi, Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí Edomu ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí, lórí òkè Filistia ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.” Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi? Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu? Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀. Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́. Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú, nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni. Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.