Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀,
wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀.
Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀,
wọ́n sì dán Ọlọrun wò.
Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè,
ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n.
Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó,
ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA.
Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì,
ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀.
Iná sọ láàrin wọn,
ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run.
Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu,
wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà.
Wọ́n gbé ògo Ọlọrun
fún ère mààlúù tí ń jẹ koríko.
Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn,
tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti,
ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu,
ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa.
Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run,
bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀,
tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀,
láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run.
Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà,
wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA.
Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn,
wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA.
Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọn
pé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀,
ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiri
àwọn orílẹ̀-èdè.
Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori,
wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú.
Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú,
àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.
Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn,
àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró.
A sì kà á kún òdodo fún un,
láti ìrandíran títí lae.