O. Daf 106:13-31
O. Daf 106:13-31 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nwọn kò pẹ igbagbe iṣẹ rẹ̀: nwọn kò si duro de imọ̀ rẹ̀. Nwọn si ṣe ifẹkufẹ li aginju, nwọn si dan Ọlọrun wò ninu aṣálẹ̀. O si fi ifẹ wọn fun wọn; ṣugbọn o rán rirù si ọkàn wọn. Nwọn ṣe ilara Mose pẹlu ni ibudo, ati Aaroni, ẹni-mimọ́ Oluwa. Ilẹ là, o si gbé Datani mì, o si bò ẹgbẹ́ Abiramu mọlẹ. Iná si ràn li ẹgbẹ́ wọn; ọwọ́ iná na jó awọn enia buburu. Nwọn ṣe ẹgbọrọ malu ni Horebu, nwọn si foribalẹ fun ere didà. Bayi ni nwọn pa ogo wọn dà si àworan malu ti njẹ koriko. Nwọn gbagbe Ọlọrun, Olugbala wọn, ti o ti ṣe ohun nla ni ilẹ Egipti. Iṣẹ iyanu ni ilẹ Hamu, ati ohun ẹ̀ru lẹba Okun pupa. Nitorina li o ṣe wipe, on o run wọn, iba máṣe pe Mose, ayanfẹ rẹ̀, duro niwaju rẹ̀ li oju-ẹya na, lati yi ibinu rẹ̀ pada, ki o má ba run wọn. Nitõtọ, nwọn kò kà ilẹ didara nì si, nwọn kò gbà ọ̀rọ rẹ̀ gbọ́: Ṣugbọn nwọn nkùn ninu agọ wọn, nwọn kò si feti si ohùn Oluwa. Nitorina li o ṣe gbé ọwọ rẹ̀ soke si wọn, lati bì wọn ṣubu li aginju: Lati bì iru-ọmọ wọn ṣubu pẹlu lãrin awọn orilẹ-ède, ati lati fún wọn ka kiri ni ilẹ wọnni. Nwọn da ara wọn pọ̀ pẹlu mọ Baali-Peoru, nwọn si njẹ ẹbọ okú. Bayi ni nwọn fi iṣẹ wọn mu u binu: àrun nla si fó si arin wọn. Nigbana ni Finehasi dide duro, o si ṣe idajọ: bẹ̃li àrun nla na si dá. A si kà eyi na si fun u li ododo lati irandiran titi lai.
O. Daf 106:13-31 Yoruba Bible (YCE)
Kò pẹ́ tí wọ́n tún fi gbàgbé iṣẹ́ rẹ̀, wọn kò sì dúró gba ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọ́n ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ní aṣálẹ̀, wọ́n sì dán Ọlọrun wò. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n bèèrè, ṣugbọn ó fi àìsàn ajẹnirun ṣe wọ́n. Nígbà tí wọ́n ṣe ìlara sí Mose ninu ibùdó, ati sí Aaroni, ẹni mímọ́ OLÚWA. Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì, ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀. Iná sọ láàrin wọn, ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run. Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu, wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà. Wọ́n gbé ògo Ọlọrun fún ère mààlúù tí ń jẹ koríko. Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti, ó ṣe, iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu, ati ohun ẹ̀rù lẹ́bàá òkun pupa. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run, bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀, tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀, láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run. Wọn kò bìkítà fún ilẹ̀ dáradára náà, wọn kò sì ní igbagbọ ninu ọ̀rọ̀ OLUWA. Wọ́n ń kùn ninu àgọ́ wọn, wọn kò sì fetí sí ohùn OLUWA. Nítorí náà, ó gbé ọwọ́ sókè, ó búra fún wọn pé òun yóo jẹ́ kí wọ́n kú sí aṣálẹ̀, ati pé òun yóo fọ́n àwọn ìran wọn káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori, wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú. Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú, àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn, àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró. A sì kà á kún òdodo fún un, láti ìrandíran títí lae.
O. Daf 106:13-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n wọn kò pẹ́ gbàgbé ohun tí o ṣe wọn kò sí dúró gba ìmọ̀ràn rẹ Nínú aginjù ni wọ́n tí ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú aṣálẹ̀, wọ́n dán Ọlọ́run wò Nígbà náà, ó fún wọn ní ohun tí wọ́n béèrè fún ṣùgbọ́n ó rán àìsàn búburú sí wọn. Nínú ibùdó ni wọ́n ṣe ìlara Mose pẹ̀lú Aaroni, ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ sí OLúWA. Ilẹ̀ la ẹnu ó sì gbé Datani mì ó bo ẹgbẹ́ Abiramu mọ́lẹ̀ Ọwọ́ iná yọ ní ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; iná jo àwọn ènìyàn búburú. Ní Horebu wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù wọ́n sì sin òrìṣà tí a ṣe láti ara irin. Wọ́n pa ògo wọn dà sí àwòrán màlúù, tí ń jẹ koríko. Wọ́n gbàgbé Ọlọ́run, ẹni tí ó gbà wọ́n ẹni tí ó ti ṣe ohun ńlá ní Ejibiti, Iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Hamu àti ohun ẹ̀rù ni ẹ̀bá Òkun pupa Bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ wí pé, òun yóò pa wọ́n run bí kò bá ṣe ti Mose, tí ó yàn, tí ó dúró níwájú ẹ̀yà náà tí ó pa ìbínú rẹ̀ mọ́ láti má pa wọ́n run mọ́. Nígbà náà, wọ́n kẹ́gàn ilẹ̀ dídára náà wọn kò gba ìlérí rẹ̀ gbọ́. Wọ́n ń kùn nínú àgọ́ wọn wọn kò sì gbọ́rọ̀ sí OLúWA. Bẹ́ẹ̀ ni ó búra fún wọn nípa gbígbé ọwọ́ rẹ̀ sókè kí òun lè jẹ́ kí wọn ṣubú nínú aginjù, Láti jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣubú lára orílẹ̀-èdè láti fọ́n wọn káàkiri lórí ilẹ̀. Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali-Peori, wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí a rú sí àwọn òkú òrìṣà Wọ́n mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú ohun búburú tí wọn ń ṣe àjàkálẹ̀-ààrùn jáde láàrín wọn. Ṣùgbọ́n Finehasi dìde láti dá sí i, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dáwọ́ dúró lọ́gán A sì ka èyí sí òdodo fún un àti fún àwọn ìrandíran tí ń bọ̀