ORIN DAFIDI 105:1-11

ORIN DAFIDI 105:1-11 YCE

Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, ẹ pe orúkọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ẹ kọrin sí i, ẹ kọ orin ìyìn sí i, ẹ sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ribiribi rẹ̀. Ẹ máa fi orúkọ mímọ́ rẹ̀ yangàn, kí ọkàn àwọn tí ń wá OLUWA ó máa yọ̀. Ẹ wá ojurere OLUWA ati agbára rẹ̀, ẹ máa wá ojurere rẹ̀ nígbà gbogbo. Ẹ ranti iṣẹ́ ribiribi tí ó ti ṣe, ẹ ranti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ati ìdájọ́ rẹ̀. Ẹ̀yin ọmọ Abrahamu, iranṣẹ rẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀. OLUWA ni Ọlọrun wa, ìdájọ́ rẹ̀ kárí gbogbo ayé. Títí lae ni ó ń ranti majẹmu rẹ̀, ó ranti àṣẹ tí ó pa fún ẹgbẹẹgbẹrun ìran, majẹmu tí ó bá Abrahamu dá, ìlérí tí ó fi ìbúra ṣe fún Isaaki, tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí òfin, àní fún Israẹli gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé, ó ní: “Ẹ̀yin ni n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún, yóo jẹ́ ìpín yín tí ẹ óo jogún.”