ORIN DAFIDI 102:1-5

ORIN DAFIDI 102:1-5 YCE

Gbọ́ adura mi, OLUWA; kí o sì jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ. Má yọwọ́ lọ́ràn mi lọ́jọ́ ìṣòro! Dẹtí sí adura mi; kí o sì tètè dá mi lóhùn nígbà tí mo bá ké pè ọ́. Nítorí ọjọ́ ayé mi ń kọjá lọ bí èéfín, eegun mi gbóná bí iná ààrò. Ìdààmú bá ọkàn mi, mo rọ bíi koríko, tóbẹ́ẹ̀ tí mo gbàgbé láti jẹun. Nítorí igbe ìrora mi, mo rù kan eegun.